Show Overview

1- Idanileko yi soro nipa bi arinrin-ajo ati alaare yoo se maa ki irun won laini fi wole tabi lo o lara tayo asiko re.2- Kiki irun rakah merin ni meji ni ori irinajo ati ki alaare fi aawe sile ninu osu Ramadan ki o si gba a pada nigbati ara re ba ya gbogbo eleyi je irorun ti Olohun se fun awa Musulumi ti O si fe ki a maa je anfaani re nitoripe irorun ni Olohun fe fun wa ninu Esin Islam.3- Alaye ni ekunrere lori awon idajo irun onirin-ajo, igba ti yoo maa bere si din irun re ku ati asiko ti yoo fi din irun ku, bakannaa oro waye lori awon isesi onirin-ajo nipa awon irun ti yoo maa pe ati eyi ti yoo maa din ku.4- Oro waye ninu apa kerin yi lori idajo kiki irun meji papo fun onirin-ajo ati awon ohun ti o le se okunfa kiki irun papo bakannaa fun eni ti kii se onirin-ajo.5- Alaye nipa awon iruju ti o maa n waye lori irun arinrin-ajo ati irun alaare, bakannaa nipa pataki iranti Olohun ni gbogbo igba.

Artist

Sharafuddeen Gbadebọ Raji

Category

Islam, Podcasts, Religion & Spirituality, Education
Untitled
Unknown
00:00 / 00:00